ORIN DAFIDI 37:1-3
[1]MÁṢE ikanra nitori awọn oluṣe-buburu, ki iwọ ki o máṣe ilara nitori awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.
(A Psalm of David.) Fret not thyself because of evildoers, neither be thou envious against the workers of iniquity.
[2]Nitori ti a o ke wọn lulẹ laipẹ bi koriko, nwọn o si rọ bi eweko tutù.
For they shall soon be cut down like the grass, and wither as the green herb.
[3]Gbẹkẹle Oluwa, ki o si ma ṣe rere; ma gbe ilẹ na, ki o si ma huwa otitọ.
Trust in the LORD, and do good; so shalt thou dwell in the land, and verily thou shalt be fed.
HEBERU 3:18-19
[18]Awọn tali o si bura fun pe nwọn kì yio wọ̀ inu isimi on, bikoṣe fun awọn ti kò gbọran?
And to whom sware he that they should not enter into his rest, but to them that believed not?
[19]Awa si ri pe nwọn kò le wọ̀ inu rẹ̀ nitori aigbagbọ́.
So we see that they could not enter in because of unbelief.
AISAYA 42:1-2
[1]WÒ iranṣẹ mi, ẹniti mo gbéro: ayànfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si; mo ti fi ẹmi mi fun u: on o mu idajọ wá fun awọn keferi.
Behold my servant, whom I uphold; mine elect, in whom my soul delighteth; I have put my spirit upon him: he shall bring forth judgment to the Gentiles.
[2]On kì yio kigbé, bẹ̃ni kì yio gbé ohùn soke, bẹ̃ni kì yio jẹ ki a gbọ́ ohùn rẹ̀ ni igboro.
He shall not cry, nor lift up, nor cause his voice to be heard in the street.
JOṢUA 5:6
[6]Nitoriti awọn ọmọ Israeli rìn li ogoji ọdún li aginjù, titi gbogbo iran na, ani awọn ologun, ti o jade ti Egipti wá fi run, nitoriti nwọn kò gbà ohùn OLUWA gbọ́: awọn ti OLUWA bura fun pe, on ki yio jẹ ki wọn ri ilẹ na, ti OLUWA bura fun awọn baba wọn lati fi fun wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.
For the children of Israel walked forty years in the wilderness, till all the people that were men of war, which came out of Egypt, were consumed, because they obeyed not the voice of the LORD: unto whom the LORD sware that he would not shew them the land, which the LORD sware unto their fathers that he would give us, a l